Bí o ti le yọ àkántì rẹ kúrò

Ṣé o fẹ́ gba sinmi lọ́wọ́ X? Ó nyé wa. Nígbà míràn ó dára kí o gbé ìgbésẹ̀ kan padà sẹ́yìn nínú ohun gbogbo tí ń ṣẹlẹ̀. Tàbí tí o bá ń wá ìsinmi títí láé, a le ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Tẹ̀lé àwọn ìtọ́ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé wa lórí bí o ti le ṣe ìyọkúrò—tàbí pa—àkántì X rẹ rẹ́.

Àkíyèsí: Tí o bá nní ìṣòro àkántì (fún àpẹẹrẹ. àwọn Twíìtì tó sọnùolùtẹ̀lé tàbí àwọn ònkà ìtẹ̀lé àìtọ̀nàÀwọn Ìfiránṣẹ́ Tààrà tí ó mú ìfura lọ́wọ́ tàbí àbọ̀dè àkántì tó le wáyé), yíyọkúrò àti àtúnmúṣiṣẹ́ àkántì rẹ kò níí yanjú rẹ̀. Jọ̀wọ́ tọ́ka sí àwọn àròkọ yíyánjú ìṣòro tàbí kí o kàn sí Àtìlẹ́yìn X.

 

Yíyọkúrò dojúkọ pípa àkántì Twitter rẹ rẹ́

Yíyọ àkántì Twitter rẹ kúro ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti pa àkántì rẹ rẹ́ títí láí. Yíyọkúrò máa nwà fún ọjọ́ 30. Tí o kò bá ráàyèsí àkántì rẹ láàrín ìgbà ìyọkúrò ọlọ́jọ́ 30, a pa àkántì rẹ rẹ́ àti wípé orúkọ aṣàmúlò rẹ kò níí ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àkántì rẹ mọ́.
 

 

Yíyọ àkántì Twitter rẹ kúrò

Yíyọkúrò ni ó máa nbẹ̀rẹ̀ ìlànà iṣẹ́láti pa àkantì Twitter rẹ rẹ́ títí láí. Ìgbésẹ̀ yìí ni ó máa nbẹ̀rẹ̀ fèrèsé ọlọ́jọ́ 30 tí ń fún ọ ní àyè láti pinnu tí o bá fẹ́ tún mú àkántì rẹ ṣiṣẹ́.

Yíyọ àkántì Twitter rẹ kúrò ntúmọ̀ sí pé orúkọ aṣàmúlò rẹ (tàbí “hándù”) àti ìjúwe gbogbogbò kò ní ṣe é wò lórí twitter.com, Twitter fún iOS tàbí Twitter fún Android. 
 

 

Pípa àkántì Twitter rẹ rẹ́

Lẹ́yìn fèrèsé yíyọkúrò ọlọ́jọ́-30 rẹ, àkántì Twitter rẹ ni a parẹ́ títí láí. Nígbà tí o kò bá wọlé sínú àkántì rẹ ní àkókò fèrèsé ọlọ́jọ́-30 náà, ó njẹ́ ká mọ̀ pé o fẹ́ pa àkántì Twitter rẹ rẹ́ títí láí. Ní kété tí àkántì rẹ bá ti parẹ́, àkántì rẹ kò sí lórí àwọn ẹ̀rọ wa mọ́. O kò níí le tún mú àkántì ìṣájú rẹ ṣiṣẹ́ mọ́ àti wípé o kò níí ìráàyèsí èyíkéyìí àwọn Twíìtì àtijọ́ mọ́.

Ní kété tí a bá pa àkántì rẹ rẹ́ lẹ́yìn fèrèsé ìyọkúrò ọlọ́jọ́-30 naà, orúkọ aṣàmúlò rẹ yóò wà nílẹ̀ fún ìforúkọsílẹ̀ nípa àwọn àkántì Twitter míràn.

 

Àwọn nkan tí ó wọ́pọ̀ láti mọ̀ kí o tó yọ àkántì rẹ kúrò

Ìwọ̀nyí ni àwọn ohun díẹ̀ láti fi sọ́kàn tí o bá ti pinnu láti ṣe ìyọkúrò tàbí pa àkántì Twitter rẹ rẹ́:

  • Pípa àkántì Twitter rẹ rẹ́ kò níí pa àlàyé rẹ rẹ́ nínú àwọn ẹ̀rọ ìwákiri bíi Google tàbí Bing nítorí pé Twitter kọ́ ni ó n darí àwọn sáìti náà. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìgbésẹ̀ tí o le gbé tí o bá kàn sí ẹ̀rọ ìwákiri náà.
  • Nígbà tí o bá yọ àkántì Twitter rẹ kúrò, àwọn ìdárúkọ orúkọ aṣàmúlò àkántì rẹ ní àwọn Twíìtì míràn yóò sì wà. Ṣùgbọ́n kò níí sopọ̀ mọ́ ìjúwe rẹ mọ́ nítorí pé ìjúwe rẹ kò níí sí nílẹ̀ mọ́. Tí o bá fẹ́ kí a ṣe àtúnwo àkóónú náà lábẹ́ Àwọn Òfin Twitter, o le fi tíkẹ̀tì kan kalẹ̀ níbí.
  • O kò ní láti pa àkántì rẹ rẹ́ láti yí orúkọ aṣàmúlò tàbí ímeèlì padà tó níí ṣe pẹ̀lú àkántì Twitter rẹ. Lọ sí Àlàyé àkántì láti mú ìyẹn dójú ìwọ̀n nígbàkugbà.
  • Wíwọlé sínú àkántì rẹ láàrín fèrèsé ìyọkúrò ọlọ́jọ́-30 náà ń dá àkántì rẹ padà nírọ̀rùn.
  • Tí o bá fẹ́ gba dátà Twitter rẹ láti orí ẹ̀rọ, wàá ní láti béèrè fún u kí o tó yọ àkántì rẹ kúrò. Yíyọ àkántì rẹ kúrò kò yọ dátà kúrò nínú àwọn ẹ̀rọ Twitter.
  • Twitter le mú àwọn àlàyé kan dání lórí àkántì rẹ tí a yọ kúrò láti ṣe àrídájú àìléwu àti ààbò pẹpẹ iṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí ń lo Twitter. Àfikún àlàyé ni a le rí níbí.
     

Tí o bá nní ìṣòro láti ṣe àkóso àkántì Twitter rẹ, wo àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyí fún ìṣàkóso àwọn iṣòro to wọ́pọ̀ kí o tó yàn láti pa àkántì Twitter rẹ rẹ́.

 
Bí o ti le yọ àkántì rẹ kúrò
Step 1

Fi ọwọ́ ba àwòrán àkójọ àṣàyàn ìyíkiri náà , lẹ́yìn náà fi ọwọ́ ba Àwọn ààtò àti ìpamọ́.

Step 2

Fi ọwọ́ bà Àkántì rẹ, lẹ́yìn náà fi ọwọ́ ba Yọ àkántì rẹ kúrò.

Step 3

Ka àlàyé ìyọkúrò àkántì náà, lẹ́yìn náà fi ọwọ́ ba Yọ ọ́ kúrò.  

Step 4

Tẹ ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ wọlé tí a bá ti wí fún ọ kí o sì fi ọwọ́ ba Yọ ọ́ kúrò.

Step 5

Jẹ́rìísíi wípé o fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa fífi ọwọ́ ba Bẹ́ẹ̀ni, yọ ọ́ kúrò.

Step 1

Nínú àkójọ àṣàyàn òkè, yálà wàá rí àwòrán àkójọ àṣàyàn ìyíkiri kan  tàbí àwòrán ìjúwe rẹ. Fi ọwọ́ bà èyíkéyìí àwòrán tí o ní, kí o sì fi ọwọ́ baÀwọn Ètò àti ìpamọ́.

Step 2

Fi ọwọ́ bà Àkántì, lẹ́yìn náà fi ọwọ́ ba Yọ àkántì rẹ kúrò.

Step 3

Ka àlàyé ìyọkúrò àkántì náà, lẹ́yìn náà fi ọwọ́ ba Yọ ọ́ kúrò.  

Step 4

Tẹ ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ wọlé tí a bá ti wí fún ọ kí o sì fi ọwọ́ ba Yọ ọ́ kúrò.

Step 5

Jẹ́rìísíi wípé o fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa fífi ọwọ́ ba Bẹ́ẹ̀ni, yọ ọ́ kúrò.

Step 1

Tẹ lórí àwòrán síi náà  kí o sì tẹ Àwọn ààtò àti ìpamọ́ láti inú àkójọ àṣàyàn ìfàsílẹ̀.

Step 2

Láti táàbù Àkántì rẹ náà, tẹ lórí Yọ àkántì rẹ kúrò.

Step 3

Ka àlàyé ìyọkúrò àkántì náà, lẹ́yìn náà tẹ Yọ ọ́ kúrò

Step 4

Tẹ ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ nígbà tí a bá wí fún ọ kí o sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé o fẹ́ tẹ̀ síwájú nípa títẹ bọ́tìnnì Yọ àkántì kúrò.


Tí o bá ríi wípé o ti ṣàárò X kò sì tíì pé ọjọ́ 30, ṣáà wọlé kí o sì tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí láti tún mú àkántì rẹ ṣiṣẹ́.
 

 

Àwọn ìforúkọsílẹ̀ àti yíyọ àkántì kúrò 

Yíyọ àkántì X rẹ kúrò kò fagi lé ìforúkọsílẹ̀ X ní aládàáṣe. Tí o bá ní èyíkéyìí ìforúkọsílẹ̀ tí ó nṣiṣẹ́ tí a sanwó fún (fún àpẹẹrẹ X Blue, àwọn Ìtẹ̀lé Dídára) tí o rà nípasẹ̀ áàpù X, wọn yóò máa wà lójú iṣẹ́. O le ṣe àkóso àwọn ìforúkọsílẹ̀ yìí nípasẹ̀ pẹpẹ náà níbi tí o ti kọ́kọ́ fi orúkọ sílẹ̀. Àwọn ìforúkọsílẹ̀ tí a rà lórí X.com yóò di ìfagilé ní aládàáṣe lẹ́yìn tí o bá ti yọ àkántì rẹ kúrò.

Bí o ti le fagi lé ìforúkọsílẹ̀ X Blue

Bí o ti le fagi lé ìforúkọsílẹ̀ àwọn Ìtẹ̀lé Dídára

 

Àwọn Ìbéèrè Ìgbàdégbà

Ṣé yíyọ Twitter kúrò yóò tún pa àwọn ìfiránṣẹ́ tààrà mi rẹ́?

Ní àkókò ìyọkúrò ọlọ́jọ́ 30 náà, a kò níí pa àwọn ìfiránṣẹ́ tààrà rẹ rẹ́. Nígbà tí àkókò ìyọkúrò náà bá dópin tí a sì pa àkántì rẹ rẹ́, àwọn ìfiránṣẹ́ tààrà tí o ti fi ṣọwọ́ ni a ó tún parẹ́.

Mo yọ àkántì mi kúrò, ṣùgbọ́n kínni ìdí tí ó fi tún nṣiṣẹ́ padà?

Tí o bá fún èyíkéyìí áàpù ẹlòmíràn ní àṣẹ láti ráàyèsí àkántì rẹ, o le máa gba ọ̀nà míràn wọlé láti inú áàpù míràn. Nítorí pé wíwọlé sínú Twitter tún nmú kí àkántì rẹ ṣiṣẹ́ ní aládàáṣe, ṣe àrídájú wípé o fagi lé ìráàyèsí áàpu ẹlomíràn sí àkántì Twitter rẹ.

Tí n kò bá ní ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé ńkọ́ nígbàtí mo gbìyànjú láti yọ ọ́ kúrò?

Tí o kò bá níi lọ́wọ́, tàbí o ń gba ìfiránṣẹ́ kan tí kò tọ̀nà, o le ní láti ṣe àtúntò ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ. Gbìyànjú bíbéèrè ímeèlì àtúntò ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé.

Mo béèrè ímeèlì àtúntò ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé kan, ṣùgbọ́n tí mo bá pàdánù ìráàyèsí àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì mi tí mo lò láti ṣètò àkántì mi nkọ́?

Tí o bá pàdánù ìráàyèsí àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì tí ó sopọ̀ mọ́ àkántì Twitter rẹ, wàá ní láti kàn sí olùpèsè iṣẹ́ ímeèlì rẹ. Gba ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ìráàyèsí àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ. Yíyọkúrò jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tí a gbọ́dọ̀ gbé nípasẹ̀ ẹni tí ó ni àkántì náà tí a jẹ́rìísí tàbí nípa ìbéèrè ẹni tí o ní àkántì náà tí a jẹ́rìísí. Àyàfi tí o bá kàn sí wa láti inú àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì tí a jẹ́rìísí (tàbí ní ìráàyèsí nọ́mbà alágbèéká tí a jẹ́rìísí lórí àkántì náà), a kò le yọ àkántì náà kúrò lórúkọ rẹ. Tí o bá ní ìráàyèsí nọ́mbà alágbèéká tí a jẹ́rìísí lórí àkántì rẹ, lẹ́yìn náà o le béèrè àtúntò ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé.

Báwo ni kí ń ti yọ àkántì ìdádúró tàbí àtìpa mi kúrò?

Láti yọ àkántì àtìpa tàbí ìdádúró rẹ kúrò, jọ̀wọ́ fa ìbéèrè kan kalẹ̀ níbí. A tún le darí àwọn ìbéère sí àwọn ẹni kíkàn sí tí a tòkọ lábẹ́ Abala “Bí O Ti le Kàn sí Wa” nínú Ìlànà Ìpamọ́ wa.

O tún le gba ìrànlọ́wọ́ láti ṣí àkántì rẹ. Gba àlàyé síi lórí ìṣàkóso àkántì ìdádúró tàbí àtìpa rẹ, èyí tó pẹ̀lú fífi ẹ̀bẹ̀ kan kalẹ̀.

Pín àròkọ yìí