Ṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àkántì mi tí ó gba ìbọ̀dè

Tí àkántì rẹ bá ti gba ìbọ̀dè ṣùgbọ́n tí o ṣì le wọlé, ojú-ewé yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáàbò bo àkántì rẹ kí o sì dẹ́kun àwọn ìwà tí o kò fẹ́. 

 

Ṣé àkántì mi ti gba ìbọ̀dè?


Ṣé o ti:

  • Ṣe àkíyèsí àwọn Twíìtì tí o kò retí nípa àkántì rẹ
  • Rí àwọn Ìfiránṣẹ́ Tààrà tí a kò ní lọ́kàn tí a fi ránṣẹ́ láti àkántì rẹ
  • Kíyèsí àwọn ìwà àkántì míràn tí o kò ṣe tàbí fi ọwọ́ sí (bíi títẹ̀lé, àìtẹ́lé tàbí dídínà)
  • Gba ìfitónilétí kan láti ọ̀dọ̀ wa tó nwípé àkántì rẹ le ti gba ìbọ̀dè
  • Gba ìfitónilétí kan láti ọ̀dọ̀ wa tó nwípé àlàyé àkántì rẹ ti yí padà, kìí sìí ṣe ìwọ ni o yíi pada
  • Kíyèsíi pé ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ kò ṣiṣẹ́ mọ́ a sì nwí fún ọ pé kí o yíi padà

 

Tí o bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ni sí ìkankan lókè yìí, jọ̀wọ́ gbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí:


1. Pààrọ̀ ọ̀rọ̀ ìgbaniwolé rẹ

Jọ̀wọ́ pààrọ̀ ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ lójú ẹsẹ̀ láti inú táàbù Ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé nínú àwọn ààtò. Tí o bá jáde, lọ sí Wọlé kí o sì tẹ lórí Gbàgbé Ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé láti ṣe àtúntò ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ. Jọ̀wọ́ yan ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé kan tí ó lágbára tí o kò tíi lò tẹ́lẹ̀. 

2. Ṣe àrídájú wípé àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ ní ààbò

Ṣe àrídájú wípé àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì tó so pọ̀ mọ́ àkántì rẹ ní ààbò àti wípé ìwọ ni ẹnìkan ṣoṣo tó le ráàyè síi. O le yí àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ padà láti inú áàpù X rẹ (iOS tàbí Android) tàbí nípa wiwọlé sórí X.com àti ṣíṣe àbẹ̀wò sí táàbù àwọn ààtò Àkántì. Ṣe àbẹ̀wò sí àròkọ yií fún àwọn ìtọ́ni fún mímú àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì rẹ dójú ìwọ̀n, kí o sì rí àròkọ yìí fún àfikún ìmọ̀ràn ààbo àkántì ímeelì.

3. Yọ àwọn ìsopọ̀ mọ́ àwọn àtòjò-èto ẹlòmíràn kúrò

Nígbà tí o bá wọlé, ṣe abẹ̀wò sí Àwọn áàpù nínú àwọn ààtò rẹ. Fagi lé ìráàyèsí aplikéṣàn ẹlòmíràn kúrò èyí tí o kò dámọ̀.

4. Mú ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ dójú ìwọ̀n nínú àwọn aplikéṣàn ẹlòmíran tí o fi ọkàn tán

Tí aplikéṣàn òde kan tí o fi ọkàn tán bá ń lo ọ̀rọ̀ ìgbaniwolé X rẹ, ṣe àrídájú láti mú ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ dójú ìwọ̀n nínú aplikéṣàn náà. Bí bẹ́ẹ̀kọ́, a le tì ọ̀nà mọ́ ọ fún ìgbà díẹ̀ kúrò nínú àkántì rẹ nítorí àwọn ìgbìyànjú ìwọlé tí ó kùnà

Àkántì rẹ gbọ́dọ̀ ní ààbo báyìí, àti wípé kò yẹ kí o rí àwọn ìwà àkántì tí a kò rétí mọ́ láti ìsinsìnyí lọ. Tí o bá sì ń dojúkọ àwọn ìṣòro, jọ̀wọ́ fa ìbéèrè àtìlẹ́yìn kan kalẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.
 

5. Kàn sí Àtìlẹ́yìn tí o bá sì nílò ìrànlọ́wọ́

Tí o kò bá tíì le fi àṣẹ wọlé síbẹ̀ lẹ́yìn tí o gbìyànjú àtúntò ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé, kàn sí wa nípa fífa Ìbéèrè Àtìlẹ́yìnkan kalẹ̀. Ṣe àrídájú láti lo àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì tí a sopọ̀ mọ́ pẹ̀lú  àkántì X tó gbàbọ̀dè; lẹ́yìn náà a ó fi àfikún àlàyé àti ìtọ̀ni ránṣẹ́ sí àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì náà. Nígbà tí o bá ń fa ìbéèrè àtìlẹ́yìn rẹ kalẹ̀ jọ̀wọ́ ṣe àfikún orúkọ aṣàmúlò rẹ àti déètì tí o ráàyè wọlé sínú àkántì rẹ gbẹ̀yìn.


Kọ́ síi nípa ohun tí o le ṣe tí o bá ti pàdánù ìráàyèsí àkánti ímeèlì náà tó sopọ̀ mọ́ àkántì X rẹ.

 

Dáàbòbò àkántì rẹ pẹ̀lú àwọn ìṣọ́ra tí ó rọrùn


Tí àkántì rẹ bá ti gba ìbọ̀dè, gbé àwọn àfikún ìgbésẹ̀ ìṣọ́ra wọ̀nyí:

  • Pa èyíkéyìí Twíìtì tí o kò fẹ́ rí tí wọ́n fi ṣọwọ́ nígbà tí àkántì rẹ gba ìbọ̀dè.
  • Ṣe àyẹ̀wò àwọn kọ̀npútà rẹ fún àkóràn àti ìtànjẹ, pàápàá jùlọ àwọn ìwà àìgbàṣẹ ti àkántì èyí tí a ń fi ṣọwọ́ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti ṣe àyípadà ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé náà.
  • Fi àwọn ohun ààbò sórí ìlànà ìṣiṣẹ́ rẹ àti àwọn àtòjọ-èto.
  • Nígbà gbogbo máa lo ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé tuntun, tí ó lágbára tí o kò lò níbò míràn tí yóò sì nira láti dábàá.
  • Gbé lílo Ìfàṣẹsí onípele-méjì yẹ̀wò. Dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé kan ṣoṣo, ìjẹ́rìísí ìwọlé máa ń ṣe àfihàn àyẹ̀wò keji láti ṣe àrídájú wípé ìwọ àní ìwọ nìkan ṣoṣo ló le ráàyèsí àkántì X rẹ.  Ó jẹ́ ẹ̀yà ààbò tó ṣe kókó èyítí ń ṣàfikún ipele ààbò míràn sí àkántì rẹ ó sì ń dín ewu ìráyèsí tí a kò fún ní àṣẹ kù lọ́pọ̀lọpọ̀.
  • Máṣe ṣàpínlò àwọn ohun ẹ̀rí fi àṣẹ wọlé rẹ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ìṣe tó dára láti dín ewu ìgbàbọ̀dè àkántì rẹ kù.

O le rí àfikún ìwífúnni nínú ojú-ewéàwọn ìmọ̀ràn ààbò àkántì wa.

 

Báwo ni àwọn àkánti ṣe ń gba ìbọ̀dè? 


Àwọn àkántì le gba ìbọ̀dè tí o bá ti fi orúkọ aṣàmúlò àti ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ sínú wẹ́ẹ̀busáìti tàbí àwọn aplikéṣàn ẹlòmíràn tí ń tanni jẹ, tí àkántì X rẹ bá gbọ̀jẹ̀gẹ́ nítorí ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé tí ó rọrùn, tí àkóràn tàbí ète ìtanijẹ lórí kọ̀npútà rẹ bá ń gba àwọn ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé, tàbí tí o bá wà lórí nẹ́tíwọ̀kì tó ti gba ìbọ̀dè.

Àwọn ìmú dójú ìwọ̀n tí a kò lérò kìí túmọ̀ sí wípé àkántì rẹ ti gbàbọ̀dè ní gbogbo ìgbà. Nígbà kọ̀ọ̀kan, aplikéṣàn ẹlòmíràn kan le ní àṣìṣe kan tí ó nṣe okùnfà ìwà àìlérò. Tí o bá rí ìwà àjòjì, yíyí ọ̀rọ̀ ìgbaniwọlé rẹ padà àti/tàbí yíyọ àwọn ìsopọ̀ kúrò yóò dẹ́kun rẹ̀, nítorí aplikéṣàn náà kò níí ráàyèsí àkántì rẹ mọ́.

Ó dára jùlọ láti gbé ìgbésẹ̀ ní kété tí àwọn ìmúdójú ìwọ̀n bá ti nfi ara hàn nínú àkántì rẹ tí o kò fi ṣọwọ́ tàbí fi ọwọ́ sí. 

Pín àròkọ yìí